1. Kor 16:19-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Awọn ijọ ni Asia kí nyin. Akuila ati Priskilla kí nyin pupọ ninu Oluwa, pẹlu ijọ ti o wà ni ile wọn.

20. Gbogbo awọn arakunrin kí nyin. Ẹ fi ifẹnukonu mimọ́ kí ara nyin.

21. Ikíni ti emi Paulu, lati ọwọ́ emi tikarami wá.

22. Bi ẹnikẹni kò ba fẹ Jesu Kristi Oluwa, ẹ jẹ ki o di Anatema. Maranata.

23. Õre-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa ki o pẹlu nyin.

24. Ifẹ mi wà pẹlu gbogbo nyin ninu Kristi Jesu. Amin.

1. Kor 16