11. Nitorina ki ẹnikẹni máṣe kẹgan rẹ̀. Ṣugbọn ẹ sìn i jade lọna-ajò li alafia, ki on ki o le tọ̀ mi wá: nitoriti emi nwò ọ̀na rẹ̀ pẹlu awọn arakunrin.
12. Ṣugbọn niti Apollo arakunrin wa, mo bẹ ẹ pupọ ki o tọ̀ nyin wá pẹlu awọn arakunrin: ṣugbọn kì iṣe ifẹ rẹ̀ rara lati wá nisisiyi; ṣugbọn on o wá nigbati o ba ni akokò ti o wọ̀.
13. Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.
14. Ẹ mã fi ifẹ ṣe gbogbo nkan nyin.