1. Kor 10:26-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Nitoripe ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkún rẹ̀.

27. Bi ọkan ninu awọn ti kò gbagbọ́ ba pè nyin sibi àse, bi ẹnyin ba si fẹ ilọ; ohunkohun ti a ba gbé kalẹ niwaju nyin ni ki ẹ jẹ, laibere ohun kan nitori ẹri-ọkàn.

28. Ṣugbọn bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, A ti fi eyi ṣẹbọ, ẹ máṣe jẹ ẹ nitori ẹniti o fi hàn nyin, ati nitori ẹri-ọkàn (nitoripe ti Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀):

29. Mo ni, ẹri-ọkàn kì iṣe ti ara rẹ, ṣugbọn ti ẹnikeji rẹ: nitori ẽṣe ti a fi fi ẹri-ọkàn ẹlomiran dá omnira mi lẹjọ?

30. Bi emi bá fi ọpẹ jẹ ẹ, ẽṣe ti a fi nsọ̀rọ mi ni buburu nitori ohun ti emi dupẹ fun?

31. Nitorina bi ẹnyin ba njẹ, tabi bi ẹnyin ba nmu, tabi ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.

32. Ẹ máṣe jẹ́ ohun ikọsẹ, iba ṣe fun awọn Ju, tabi fun awọn Hellene, tabi fun ijọ Ọlọrun:

33. Ani bi emi ti nwù gbogbo enia li ohun gbogbo, laiwá ere ti ara mi, bikoṣe ti ọpọlọpọ, ki a le gbà wọn lã.

1. Kor 10