1. Joh 5:16-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bi ẹnikẹni ba ri arakunrin rẹ̀ ti ndá ẹ̀ṣẹ ti kì iṣe si ikú, on o bère, On o si fun ni ìye fun awọn ti ndá ẹ̀ṣẹ ti ki iṣe si ikú. Ẹṣẹ kan mbẹ si ikú: emi kò wipe ki on ki o gbadura fun eyi.

17. Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ: ẹṣẹ̀ kan sì mbẹ ti ki iṣe si ikú.

18. Awa mọ̀ pe ẹnikẹni ti a bí nipa ti Ọlọrun kì idẹṣẹ: ṣugbọn ẹniti a bí nipa ti Ọlọrun a mã pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni buburu nì ki si ifọwọ́kàn a.

19. Awa mọ̀ pe ti Ọlọrun ni wa, ati gbogbo aiye li o wa ni agbara ẹni buburu nì.

20. Awa si mọ̀ pe Ọmọ Ọlọrun de, o si ti fi òye fun wa, ki awa ki o le mọ̀ ẹniti iṣe otitọ, awa si mbẹ ninu ẹniti iṣe otitọ, ani ninu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. Eyi li Ọlọrun otitọ, ati ìye ainipẹkun.

1. Joh 5