28. Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni:
29. Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi.
30. Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.
31. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi:
32. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.