12. Ati agbàla nla yikakiri pẹlu jẹ ọ̀wọ́ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ọ̀wọ́ kan igi idabu ti kedari, ati fun agbala ile Oluwa ti inu lọhun, ati fun iloro ile na.
13. Solomoni ọba si ranṣẹ, o si mu Hiramu lati Tire wá.
14. Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀.