13. Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia.
14. O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na.
15. Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke;
16. Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na.
17. Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ.