26. Ọba Israeli si wipe, Mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba:
27. Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi: Ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.
28. Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ipa mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!
29. Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi.
30. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà.
31. Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan.
32. O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe.
33. O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀.
34. Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ.