16. Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.
17. Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.
18. On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.
19. Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn.
20. Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin.
21. Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ.
22. Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.
23. Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.
24. Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn.