1. A. Ọba 19:20-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ?

21. O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.

1. A. Ọba 19