1. A. Ọba 18:25-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Elijah si wi fun awọn woli Baali pe, Ẹ yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara nyin, ki ẹ si tètekọ ṣe e: nitori ẹnyin pọ̀: ki ẹ si kepè orukọ awọn ọlọrun nyin, ṣugbọn ẹ máṣe fi iná si i,

26. Nwọn si mu ẹgbọrọ akọ-malu na ti a fi fun wọn, nwọn si ṣe e, nwọn si kepè orukọ Baali lati owurọ titi di ọ̀sangangan wipe, Baali! da wa lohùn. Ṣugbọn kò si ohùn, bẹ̃ni kò si idahùn. Nwọn si jó yi pẹpẹ na ka, eyiti nwọn tẹ́.

27. O si ṣe, li ọ̀sangangan ni Elijah fi wọn ṣe ẹlẹya o si wipe, Ẹ kigbe lohùn rara, ọlọrun sa li on; bọya o nṣe àṣaro, tabi on nlepa, tabi o re àjo, bọya o sùn, o yẹ ki a ji i.

28. Nwọn si kigbe lohùn rara, nwọn si fi ọbẹ ati ọ̀kọ ya ara wọn gẹgẹ bi iṣe wọn, titi ẹ̀jẹ fi tu jade li ara wọn.

1. A. Ọba 18