20. Bẹ̃ni Ahabu ranṣẹ si gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si kó awọn woli jọ si oke Karmeli.
21. Elijah si tọ gbogbo awọn enia na wá, o si wipe, Yio ti pẹ to ti ẹnyin o ma ṣiyemeji? Bi Oluwa ba ni Ọlọrun, ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin: ṣugbọn bi Baali ba ni ẹ mã tọ̀ ọ lẹhin! Awọn enia na kò si da a li ohùn ọ̀rọ kan.
22. Elijah si wi fun awọn enia na pe, Emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù ni woli Oluwa; ṣugbọn awọn woli Baali ãdọta-lenirinwo ọkunrin,
23. Nitorina jẹ ki nwọn ki o fun wa li ẹgbọrọ akọ-malu meji; ki nwọn ki o si yàn ẹgbọrọ akọ-malu kan fun ara wọn, ki nwọn ki o si ke e, ki nwọn ki o si tò o si ori igi, ki nwọn ki o má ṣe fi iná si i: emi o si tun ẹgbọrọ akọ-malu keji ṣe, emi o si tò o sori igi, emi kì o si fi iná si i.
24. Ki ẹ si kepe orukọ awọn ọlọrun nyin, emi o si kepè orukọ Oluwa: Ọlọrun na ti o ba fi iná dahùn on na li Ọlọrun. Gbogbo awọn enia na si dahùn, nwọn si wipe, O wi i re.