1. A. Ọba 16:29-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun,

30. Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ.

31. O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,

32. O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria.

33. Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu.

1. A. Ọba 16