17. Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ.
18. Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe,
19. Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi.
20. Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali.
21. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa.
22. Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa.
23. Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀.