1. NJẸ li ọdun kejidilogun Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, Abijah jọba lori Juda.
2. Ọdun mẹta li o jọba ni Jerusalemu: orukọ iya rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu.
3. O si rin ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀, ti o ti dá niwaju rẹ̀: ọkàn rẹ̀ kò si pé pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀ gẹgẹ bi ọkàn Dafidi baba rẹ̀.