Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.