Ṣugbọn iwọ pada, iwọ si ti jẹ onjẹ, iwọ si ti mu omi ni ibi ti Oluwa sọ fun ọ pe, Máṣe jẹ onjẹ, ki o má si ṣe mu omi; okú rẹ kì yio wá sinu iboji awọn baba rẹ.