1. FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi.
2. Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ.
3. Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀.
4. Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro.
5. Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ?
6. Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ.