5. Li ọjọ ọba wa, awọn ọmọ-alade ti fi oru ọti-waini mu u ṣaisàn; o nà ọwọ́ rẹ̀ jade pẹlu awọn ẹlẹgàn.
6. Nitori nwọn ti mura ọkàn wọn silẹ bi ãrò, nigbati nwọn ba ni buba: alakàra wọn sùn ni gbogbo oru; li owurọ̀ o jo bi ọwọ́-iná.
7. Gbogbo wọn gboná bi ãrò, nwọn ti jẹ awọn onidajọ wọn run; gbogbo ọba wọn ṣubu: kò si ẹnikan ninu wọn ti o ke pè mi.
8. Efraimu, on ti dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ awọn enia na; Efraimu ni akàra ti a kò yipadà.
9. Awọn alejò ti jẹ agbara rẹ̀ run, on kò si mọ̀: nitõtọ, ewú wà kakiri li ara rẹ̀, sibẹ̀ on kò mọ̀.
10. Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a.