6. Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ.
7. Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi.
8. Gileadi ni ilu awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ, a si ti fi ẹ̀jẹ bà a jẹ.
9. Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla.
10. Mo ti ri ohun buburu kan ni ile Israeli: agbère Efraimu wà nibẹ̀, Israeli ti bajẹ.
11. Iwọ Juda pẹlu, on ti gbe ikorè kalẹ fun ọ, nigbati mo ba yi igbekun awọn enia mi padà.