7. Bi a ti mu wọn pọ̀ si i to, bẹ̃ na ni nwọn si dẹ̀ṣẹ si mi to: nitorina emi o yi ogo wọn padà si itìju.
8. Nwọn jẹ ẹ̀ṣẹ awọn enia mi, nwọn si gbe ọkàn wọn si aiṣedẽde wọn.
9. Yio si ṣe, gẹgẹ bi enia, bẹ̃li alufa: emi o si bẹ̀ wọn wò nitori ọ̀na wọn, emi o si san èrè iṣẹ wọn padà fun wọn.
10. Nwọn o si jẹ, nwọn kì o si yó: nwọn o ṣe agbère, nwọn kì o si rẹ̀: nitori nwọn ti fi ati-kiyesi Oluwa silẹ.
11. Agbère ati ọti-waini, ati ọti-waini titun a ma gbà enia li ọkàn.