Hos 4:15-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bi iwọ, Israeli, ba ṣe agbère, máṣe jẹ ki Juda ṣẹ̀; ẹ má si wá si Gilgali, bẹ̃ni ki ẹ má si goke lọ si Bet-afeni, bẹ̃ni ki ẹ má si bura pe, Oluwa mbẹ.

16. Nitori Israeli ṣe agidi bi ọmọ malu alagidi; nisisiyi Oluwa yio bọ́ wọn bi ọdọ-agùtan ni ibi ayè nla.

17. Efraimu dapọ̀ mọ òriṣa: jọwọ rẹ̀ si.

18. Ohun mimu wọn di kikan: nwọn ṣe agbère gidigidi; awọn olori rẹ̀ fẹ itìju, ẹ bun u li ayè.

19. Afẹfẹ ti dè e pẹlu mọ iyẹ́ apa rẹ̀, nwọn o si tíju nitori ẹbọ wọn.

Hos 4