Hos 2:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u.

15. Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá.

16. Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi,

17. Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́.

18. Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu.

19. Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu.

Hos 2