7. Awọn enia mi si tẹ̀ si ifàsẹhin kuro lọdọ mi: bi o tilẹ̀ ṣepe nwọn pè wọn si Ọga-ogo jùlọ, nwọn kò jùmọ gbe e ga.
8. Emi o ha ṣe jọwọ rẹ lọwọ, Efraimu? emi o ha ṣe gbà ọ silẹ, Israeli? emi o ha ti ṣe ṣe ọ bi Adma? emi o ha ti ṣe gbe ọ kalẹ bi Seboimu, ọkàn mi yi ninu mi, iyọnu mi gbiná pọ̀.
9. Emi kì yio mu gbigboná ibinu mi ṣẹ, emi kì yio yipadà lati run Efraimu: nitori Ọlọrun li emi, kì iṣe enia; Ẹni-Mimọ lãrin rẹ: emi kì yio si wá ninu ibinu.
10. Nwọn o ma tẹ̀le Oluwa: on o ke ramùramù bi kiniun: nigbati on o ke, nigbana li awọn ọmọ yio wariri lati iwọ-õrun wá.