1. ÁJARA ofo ni Israeli, o nso eso fun ara rẹ̀; gẹgẹ bi ọ̀pọ eso rẹ̀ li o mu pẹpẹ pọ̀ si i; gẹgẹ bi didara ilẹ rẹ̀ ni nwọn yá ere daradara.
2. Ọkàn wọn dá meji; nisisiyi ni nwọn o jẹbi; on o wó pẹpẹ wọn lulẹ, on o si ba ere wọn jẹ.
3. Nitori nisisiyi ni nwọn o wipe, Awa kò li ọba, nitoriti awa kò bẹ̀ru Oluwa; njẹ kili ọba o ṣe fun wa?