Heb 9:7-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ṣugbọn sinu ekeji ni olori alufa nikan imã lọ lẹ̃kanṣoṣo li ọdún, kì iṣe li aisi ẹ̀jẹ, ti on fi rubọ fun ara rẹ̀ na, ati fun ìṣina awọn enia:

8. Ẹmí Mimọ́ ntọka eyi pé a kò ti iṣi ọ̀na ibi mimọ́ silẹ niwọn igbati agọ́ ekini ba duro.

9. Eyiti iṣe apẹrẹ fun igba isisiyi gẹgẹ bi eyiti a nmu ẹ̀bun ati ẹbọ wá, ti kò le mu olusin di pipé niti ohun ti ẹri-ọkàn,

10. Eyiti o wà ninu ohun jijẹ ati ohun mimu ati onirũru ìwẹ, ti iṣe ìlana ti ara nikan ti a fi lelẹ titi fi di igba atunṣe.

11. Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi.

12. Bẹ̃ni kì iṣe nipasẹ ẹ̀jẹ ewurẹ ati ọmọ malu, ṣugbọn nipa ẹ̀jẹ on tikararẹ̀ o wọ ibi mimọ́ lẹ̃kanṣoṣo, lẹhin ti o ti ri idande ainipẹkun gbà fun wa.

13. Nitori bi ẹ̀jẹ akọ malu ati ewurẹ ti a fi nwọ́n awọn ti a ti sọ di alaimọ́ ba nsọ-ni-di-mimọ́ fun iwẹnumọ ara,

14. Melomelo li ẹ̀jẹ Kristi, ẹni nipa Ẹmí aiyeraiye ti a fi ara rẹ̀ rubọ si Ọlọrun li aini àbawọn, yio wẹ̀ ẹrí-ọkàn nyin mọ́ kuro ninu okú ẹṣẹ lati sìn Ọlọrun alãye?

15. Ati nitori eyi li o ṣe jẹ alarina majẹmu titun pe bi ikú ti mbẹ fun idande awọn irekọja ti o ti wà labẹ majẹmu iṣaju, ki awọn ti a ti pè le ri ileri ogún ainipẹkun gbà.

16. Nitori nibiti iwe-ogún ba gbé wà, ikú ẹniti o ṣe e kò le ṣe aisi pẹlu.

17. Nitori iwe-ogún li agbara lẹhin igbati enia ba kú: nitori kò li agbara rara nigbati ẹniti o ṣe e ba mbẹ lãye.

18. Nitorina li a kò ṣe yà majẹmu iṣaju papa si mimọ́ laisi ẹ̀jẹ.

19. Nitori nigbati Mose ti sọ gbogbo aṣẹ fun gbogbo awọn enia gẹgẹ bi ofin, o mu ẹ̀jẹ ọmọ malu ati ti ewurẹ, pẹlu omi, ati owu ododó, ati ewe hissopu, o si fi wọ́n ati iwe pãpã ati gbogbo enia,

20. Wipe, Eyi li ẹ̀jẹ majẹmu ti Ọlọrun palaṣẹ fun nyin.

21. Bẹ gẹgẹ li o si fi ẹ̀jẹ wọ́n agọ́, ati gbogbo ohun èlo ìsin.

22. O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.

Heb 9