17. Nitori iwe-ogún li agbara lẹhin igbati enia ba kú: nitori kò li agbara rara nigbati ẹniti o ṣe e ba mbẹ lãye.
18. Nitorina li a kò ṣe yà majẹmu iṣaju papa si mimọ́ laisi ẹ̀jẹ.
19. Nitori nigbati Mose ti sọ gbogbo aṣẹ fun gbogbo awọn enia gẹgẹ bi ofin, o mu ẹ̀jẹ ọmọ malu ati ti ewurẹ, pẹlu omi, ati owu ododó, ati ewe hissopu, o si fi wọ́n ati iwe pãpã ati gbogbo enia,
20. Wipe, Eyi li ẹ̀jẹ majẹmu ti Ọlọrun palaṣẹ fun nyin.
21. Bẹ gẹgẹ li o si fi ẹ̀jẹ wọ́n agọ́, ati gbogbo ohun èlo ìsin.
22. O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji.
23. Nitorina a kò le ṣai fi iwọnyi wẹ̀ awọn apẹrẹ ohun ti mbẹ lọrun mọ́; ṣugbọn o yẹ ki a fi ẹbọ ti o san ju iwọnyi lọ wẹ̀ awọn ohun ọrun pãpã mọ́.
24. Nitori Kristi kò wọ̀ ibi mimọ́ ti a fi ọwọ́ ṣe lọ ti iṣe apẹrẹ ti otitọ; ṣugbọn o lọ si ọ̀run pãpã, nisisiyi lati farahan ni iwaju Ọlọrun fun wa:
25. Kì si iṣe pe ki o le mã fi ara rẹ̀ rubọ nigbakugba, bi olori alufa ti ima wọ̀ inu ibi mimọ́ lọ li ọdọ̃dún ti on ti ẹ̀jẹ ti ki ṣe tirẹ̀;
26. Bi bẹ̃kọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹ̃kanṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀.