Heb 7:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nitoripe bi a ti pàrọ oyè alufa, a kò si le ṣai pàrọ ofin.

13. Nitori ẹniti a nsọ̀rọ nkan wọnyi nipa rẹ̀ jẹ ẹ̀ya miran, lati inu eyiti ẹnikẹni koi jọsin ri nibi pẹpẹ.

14. Nitori o han gbangba pe lati inu ẹ̀ya Juda ni Oluwa wa ti dide; nipa ẹ̀ya ti Mose kò sọ ohunkohun niti awọn alufa.

15. O si tún han gbangba jù bẹ̃ lọ bi o ti jẹ pe alufa miran dide gẹgẹ bi Melkisedeki,

16. Eyiti a kò fi jẹ gẹgẹ bi ofin ilana nipa ti ara, bikoṣe nipa agbara ti ìye ailopin.

17. Nitori a jẹri pe, Iwọ ni alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.

18. Nitori a mu ofin iṣaju kuro, nitori ailera ati ailere rẹ̀.

19. (Nitori ofin kò mu ohunkohun pé), a si mu ireti ti o dara jù wá nipa eyiti awa nsunmọ Ọlọrun.

20. Niwọn bi o si ti ṣe pe kì iṣe li aibura ni.

Heb 7