1. NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u;
2. Ẹniti Abrahamu si pin idamẹwa ohun gbogbo fun; li ọna ekini ni itumọ rẹ̀ ọba ododo, ati lẹhinna pẹlu ọba Salemu, ti iṣe ọba alafia;
3. Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi.
4. Njẹ ẹ gbà a rò bi ọkunrin yi ti pọ̀ to, ẹniti Abrahamu baba nla fi idamẹwa ninu awọn aṣayan ikogun fun.
5. Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade.