Heb 6:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ki ẹ máṣe di onilọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti nwọn ti ipa igbagbọ́ ati sũru jogún awọn ileri.

13. Nitori nigbati Ọlọrun ṣe ileri fun Abrahamu, bi kò ti ri ẹniti o pọju on lati fi bura, o fi ara rẹ̀ bura, wipe,

14. Nitõtọ ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bibisi emi o mu ọ bisi i.

15. Bẹna si ni, lẹhin igbati o fi sũru duro, o ri ileri na gbà.

16. Nitori enia a mã fi ẹniti o pọjù wọn bura: ibura na a si fi opin si gbogbo ijiyan wọn fun ifẹsẹ mulẹ ọ̀rọ.

17. Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn.

18. Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu:

19. Eyiti awa ni bi idakọ̀ro ọkàn, ireti ti o daju ti o si duro ṣinṣin, ti o si wọ̀ inu ile lọ lẹhin aṣọ ikele;

20. Nibiti aṣaju wa ti wọ̀ lọ fun wa, ani Jesu, ti a fi jẹ Olori Alufa titi lai nipa ẹsẹ Melkisedeki.

Heb 6