1. NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ:
2. Ẹniti o le bá awọn alaimoye ati awọn ti o ti yapa kẹdun, nitori a fi ailera yi on na ká pẹlu.
3. Nitori idi eyi li o si ṣe yẹ, bi o ti nṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ fun awọn enia, bẹ̃ pẹlu ni ki o ṣe fun ara rẹ̀.
4. Kò si si ẹniti o gbà ọlá yi fun ara rẹ̀, bikoṣe ẹniti a pè lati ọdọ Ọlọrun wá, gẹgẹ bi a ti pè Aaroni.