1. NITORINA ẹnyin ará mimọ́, alabapín ìpe ọ̀run, ẹ gbà ti Aposteli ati Olori Alufa ijẹwọ wa ro, ani Jesu;
2. Ẹniti o ṣe olõtọ si ẹniti o yàn a, bi Mose pẹlu ti ṣe ninu gbogbo ile rẹ̀.
3. Nitori a kà ọkunrin yi ni yiyẹ si ogo jù Mose lọ niwọn bi ẹniti o kọ́ ile ti li ọla jù ile lọ.
4. Lati ọwọ́ enia kan li a sá ti kọ́ olukuluku ile; ṣugbọn ẹniti o kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọrun.
5. Mose nitõtọ si ṣe olõtọ ninu gbogbo ile rẹ̀, bi iranṣẹ, fun ẹrí ohun ti a o sọ̀rọ wọn nigba ikẹhin;