Heb 2:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Njẹ niwọn bi awọn ọmọ ti ṣe alabapin ara on ẹ̀jẹ, bẹ̃ gẹgẹ li on pẹlu si ṣe alabapin ninu ọkanna; ki o le ti ipa ikú pa ẹniti o ni agbara ikú run, eyini ni Eṣu;

15. Ki o si le gbà gbogbo awọn ti o ti itori ibẹru iku wà labẹ ìde lọjọ aiye wọn gbogbo.

16. Nitoripe, nitõtọ ki iṣe awọn angẹli li o ṣe iranlọwọ fun, ṣugbọn irú-ọmọ Abrahamu li o ṣe iranlọwọ fun.

17. Nitorina o yẹ pe ninu ohun gbogbo ki o dabi awọn ará rẹ̀, ki o le jẹ alãnu ati olõtọ Olori Alufa ninu ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le ṣe etutu fun ẹ̀ṣẹ awọn enia.

18. Nitori niwọnbi on tikararẹ̀ ti jiya nipa idanwo, o le ràn awọn ti a ndan wo lọwọ.

Heb 2