Heb 2:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORINA o yẹ ti awa iba mã fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ́, ki a má bã gbá wa lọ kuro ninu wọn nigbakan.

2. Nitori bi ọ̀rọ ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran si gbà ẹsan ti o tọ́;

3. Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́;

4. Ọlọrun si nfi iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu, ati onirũru iṣẹ agbara, ati ẹ̀bun Ẹmí Mimọ́ bá wọn jẹri gẹgẹ bí ifẹ rẹ̀?

5. Nitoripe ki iṣe abẹ awọn angẹli li o fi aiye ti mbọ̀ ti awa nsọrọ rẹ̀ si.

6. Ṣugbọn ẹnikan sọ nibikan wipe, Kili enia ti o fi nṣe iranti rẹ̀, tabi ọmọ enia, ti o mbẹ̀ ẹ wò?

7. Iwọ dá a rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ; iwọ fi ogo ati ọlá dé e li ade, iwọ si fi i jẹ olori iṣẹ ọwọ́ rẹ:

8. Iwọ fi ohun gbogbo sabẹ ẹsẹ rẹ̀. Nitori niti pe o fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀ kò kù ohun kan ti kò fi sabẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi awa kò iti ri pe a fi ohun gbogbo sabẹ rẹ̀.

Heb 2