5. Ẹnyin si ti gbagbé ọ̀rọ iyanju ti mba nyin sọ bi ọmọ pe, Ọmọ mi, má ṣe alainani ibawi Oluwa, ki o má si ṣe rẹwẹsi nigbati a ba nti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wi:
6. Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ, on ni ibawi, a si mã nà olukuluku ọmọ ti o gbà.
7. Ẹ mã mu suru labẹ ibawi: Ọlọrun mba nyin lo bi ọmọ ni; nitoripe ọmọ wo ni mbẹ ti baba ki ibawi?
8. Ṣugbọn bi ẹnyin ba wà li aisi ibawi, ninu eyiti gbogbo enia ti jẹ alabapin, njẹ ọmọ àle ni nyin, ẹ kì isi iṣe ọmọ.
9. Pẹlupẹlu awa ni baba wa nipa ti ara ti o ntọ́ wa, awa si mbù ọlá fun wọn: awa kì yio kuku tẹriba fun Baba awọn ẹmí ki a si yè?
10. Nitori nwọn tọ́ wa fun ọjọ diẹ bi o ba ti dara loju wọn; ṣugbọn on fun ère wa, ki awa ki o le ṣe alabapin ìwa mimọ́ rẹ̀.
11. Gbogbo ibawi kò dabi ohun ayọ̀ nisisiyi, bikoṣe ibanujẹ; ṣugbọn nikẹhin a so eso alafia fun awọn ti a ti tọ́ nipa rẹ̀, ani eso ododo.
12. Nitorina ẹ na ọwọ́ ti o rọ, ati ẽkun ailera;
13. Ki ẹ si ṣe ipa-ọna ti o tọ fun ẹsẹ nyin, ki eyiti o rọ má bã kuro lori iké ṣugbọn ki a kuku wo o san.
14. Ẹ mã lepa alafia pẹlu enia gbogbo, ati ìwa mimọ́, li aisi eyini kò si ẹniti yio ri Oluwa:
15. Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe kùna ore-ọfẹ Ọlọrun; ki gbòngbo ikorò kan ki o má ba hù soke ki o si yọ nyin lẹnu, ọ̀pọlọpọ a si ti ipa rẹ̀ di aimọ́;
16. Ki o má bã si àgbere kan tabi alaiwa-bi-Ọlọrun bi Esau, ẹniti o ti itori òkele onjẹ kan tà ogún ibí rẹ̀.
17. Nitori ẹnyin mọ̀ pe lẹhinna ní ani nigbati o fẹ lati jogun ibukun na, a kọ̀ ọ (nitori kò ri aye ironupiwada) bi o tilẹ ti fi omije wá a gidigidi.
18. Nitori ẹnyin kò wá si òke, ti a le fi ọwọ kàn, ati si iná ti njó, ati si iṣúdùdu ati òkunkun, ati iji,