Heb 11:36-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Awọn ẹlomiran si ri idanwò ti ẹsín, ati ti ìnà, ati ju bẹ̃ lọ ti ìde ati ti tubu:

37. A sọ wọn li okuta, a fi ayùn rẹ́ wọn meji, a dán wọn wò, a fi idà pa wọn: nwọn rìn kákiri ninu awọ agutan ati ninu awọ ewurẹ; nwọn di alaini, olupọnju, ẹniti a nda loro;

38. Awọn ẹniti aiye kò yẹ fun: nwọn nkiri ninu aṣálẹ, ati lori òke, ati ninu ihò ati ninu ihò abẹ ilẹ.

39. Gbogbo awọn wọnyi ti a jẹri rere sí nipa igbagbọ́, nwọn kò si ri ileri na gbà:

40. Nitori Ọlọrun ti pèse ohun ti o dara jù silẹ fun wa, pe li aisi wa, ki a má ṣe wọn pé.

Heb 11