Heb 11:21-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nipa igbagbọ́ ni Jakọbu, nigbati o nkú lọ, o súre fun awọn ọmọ Josefu ni ọ̀kọ̃kan; o si tẹriba, o simi le ori ọpá rẹ̀.

22. Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀.

23. Nipa igbagbọ́ ni awọn obi Mose pa a mọ́ fun oṣu mẹta nigbati a bí i, nitoriti nwọn ri i ni arẹwa ọmọ; nwọn kò si bẹ̀ru aṣẹ ọba.

24. Nipa igbagbọ́ ni Mose, nigbati o dàgba, o kọ̀ ki a mã pè on li ọmọ ọmọbinrin Farao;

25. O kuku yàn ati mã bá awọn enia Ọlọrun jìya, jù ati jẹ fãji ẹ̀ṣẹ fun igba diẹ;

26. O kà ẹ̀gan Kristi si ọrọ̀ ti o pọju awọn iṣura Egipti lọ: nitoriti o nwo ère na.

27. Nipa igbagbọ́ li o kọ̀ Egipti silẹ li aibẹ̀ru ibinu ọba: nitoriti o duro ṣinṣin bi ẹniti o nri ẹni airi.

28. Nipa igbagbọ́ li o dá ase irekọja silẹ, ati ibuwọ́n ẹ̀jẹ, ki ẹniti npa awọn akọbi ọmọ ki o má bã fi ọwọ́ kàn wọn.

29. Nipa igbagbọ́ ni nwọn là okun pupa kọja bi ẹnipe ni iyangbẹ ilẹ: ti awọn ara Egipti danwò, ti nwọn si rì.

30. Nipa igbagbọ́ li awọn odi Jeriko wó lulẹ, lẹhin igbati a yi wọn ká ni ijọ meje.

31. Nipa igbagbọ́ ni Rahabu panṣaga kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbati o tẹwọgbà awọn amí li alafia.

Heb 11