Hag 2:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Li ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa wá nipa Hagai woli, pe,

11. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; bère ofin lọwọ awọn alufa nisisiyi, pe,

12. Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.

13. Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́.

14. Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́.

15. Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ rò lati oni yi de atẹhìnwa, ki a to fi okuta kan le ori ekeji ninu tempili Oluwa;

16. Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni.

Hag 2