1. LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi.
2. Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare.
3. Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ.
4. Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.
5. Bẹ̃ni pẹlu, nitoriti ọti-waini li ẹtàn, agberaga enia li on, kì isi simi, ẹniti o sọ ifẹ rẹ̀ di gbigbõrò bi ipò-okú, o si dabi ikú, a kò si lè tẹ́ ẹ lọrun, ṣugbọn o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si ọdọ, o si gbá gbogbo enia jọ si ọdọ rẹ̀: