Gẹn 7:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ.

5. Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.

6. Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye.

7. Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi.

8. Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ,

9. Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.

10. O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye.

11. Li ẹgbẹta ọdún ọjọ́ aiye Noa, li oṣù keji, ni ọjọ́ kẹtadilogun oṣù, li ọjọ́ na ni gbogbo isun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun si ṣí silẹ.

12. Òjo na si wà lori ilẹ li ogoji ọsán on ogoji oru.

13. Li ọjọ́ na gan ni Noa wọ̀ inu ọkọ̀, ati Ṣemu, ati Hamu, ati Jafeti, awọn ọmọ Noa, ati aya Noa, (ati awọn aya ọmọ rẹ̀ mẹta pẹlu wọn).

Gẹn 7