4. Nitori ijọ́ meje si i, emi o mu òjo rọ̀ si ilẹ li ogoji ọsán ati li ogoji oru; ohun alãye gbogbo ti mo dá li emi o parun kuro lori ilẹ.
5. Noa si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun u.
6. Noa si jẹ ẹni ẹgbẹta ọdún nigbati kíkun-omi de si aiye.
7. Noa si wọle, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀, ati aya awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, sinu ọkọ̀, nitori kíkun-omi.
8. Ninu ẹranko mimọ́, ati ninu ẹranko ti kò mọ́, ati ninu ẹiyẹ, ati ninu ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ,
9. Nwọn wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀ ni meji meji, ati akọ ati abo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun Noa.
10. O si ṣe ni ijọ́ keje, bẹ̃ni kíkun-omi de si aiye.