Gẹn 7:18-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi.

19. Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ.

20. Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ.

21. Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia:

22. Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú.

23. Ohun alãye gbogbo ti o wà lori ilẹ li a si parun, ati enia, ati ẹran-ọ̀sin, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun, nwọn si run kuro lori ilẹ. Noa nikan li o kù, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀.

24. Omi si gbilẹ li aiye li ãdọjọ ọjọ́.

Gẹn 7