Gẹn 7:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi.

19. Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ.

20. Omi gbilẹ soke ni igbọ́nwọ mẹ̃dogun; a si bò gbogbo okenla mọlẹ.

21. Gbogbo ẹdá ti nrìn lori ilẹ si kú, ti ẹiyẹ, ti ẹran-ọ̀sin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ati gbogbo enia:

Gẹn 7