14. Awọn, ati gbogbo ẹranko ni irú tirẹ̀, ati ẹran-ọ̀sin gbogbo ni irú tirẹ̀, ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ nla ni irú tirẹ̀, ati gbogbo ẹiyẹ abiyẹ.
15. Nwọn si wọle tọ̀ Noa lọ sinu ọkọ̀, meji meji ninu ẹda gbogbo, ninu eyiti ẹmi ìye wà.
16. Awọn ti o si wọle lọ, nwọn wọle ti akọ ti abo ninu ẹdá gbogbo, bi Ọlọrun ti fi aṣẹ fun u. OLUWA si sé e mọ́ ile.
17. Ikún-omi si wà li ogoji ọjọ́ lori ilẹ; omi si nwú si i, o si mu ọkọ̀ fó soke, o si gbera kuro lori ilẹ.
18. Omi si gbilẹ, o si nwú si i gidigidi lori ilẹ; ọkọ̀ na si fó soke loju omi.
19. Omi si gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti o wà ni gbogbo abẹ ọrun, li a bò mọlẹ.