8. Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
9. Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.
10. Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
11. Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara.
12. Ọlọrun si bojuwò aiye, si kiye si i, o bajẹ; nitori olukuluku enia ti bà ìwa rẹ̀ jẹ li aiye.