7. OLUWA si wipe, Emi o pa enia ti mo ti dá run kuro li ori ilẹ; ati enia, ati ẹranko, ati ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ oju-ọrun; nitori inu mi bajẹ ti mo ti dá wọn.
8. Ṣugbọn Noa ri ojurere loju OLUWA.
9. Wọnyi ni ìtan Noa: Noa ṣe olõtọ ati ẹniti o pé li ọjọ́ aiye rẹ̀, Noa mba Ọlọrun rìn.
10. Noa si bí ọmọkunrin mẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.
11. Aiye si bajẹ niwaju Ọlọrun, aiye si kún fun ìwa-agbara.