Gẹn 50:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Njẹ nisisiyi, ẹ má bẹ̀ru: emi o bọ́ nyin, ati awọn ọmọ wẹrẹ nyin. O si tù wọn ninu, o si sọ̀rọ rere fun wọn.

22. Josefu si joko ni Egipti, on ati ile baba rẹ̀: Josefu si wà li ãdọfa ọdún.

23. Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu.

24. Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi kú: Ọlọrun yio si bẹ̀ nyin wò nitõtọ, yio si mú nyin jade kuro ni ilẹ yi, si ilẹ ti o ti bura fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.

25. Josefu si mu awọn ọmọ Israeli bura, wipe, Ọlọrun yio bẹ̀ nyin wò nitõtọ, ki ẹnyin ki o si rù egungun mi lati ihin lọ.

26. Bẹ̃ni Josefu kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún: nwọn si kùn u li ọṣẹ, a si tẹ́ ẹ sinu posi ni Egipti.

Gẹn 50