9. Enoṣi si wà li ãdọrun ọdún, o si bí Kenani:
10. Enoṣi si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé mẹ̃dogun lẹhin ti o bí Kenani, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:
11. Gbogbo ọjọ́ Enoṣi si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé marun: o si kú.
12. Kenani si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Mahalaleli:
13. Kenani si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ogoji lẹhin ti o bí Mahalaleli, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:
14. Gbogbo ọjọ́ Kenani si jẹ ẹ̃dẹgbẹrun ọdún o lé mẹwa: o si kú.
15. Mahalaleli si wà li ọgọta ọdún o lé marun, o si bí Jaredi:
16. Mahalaleli si wà li ẹgbẹrin ọdún o lé ọgbọ̀n, lẹhin ti o bí Jaredi, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin: