Gẹn 5:26-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

27. Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú.

28. Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan:

29. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú.

30. Lameki si wà li ẹgbẹta ọdún o dí marun, lẹhin ti o bí Noa, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

31. Gbogbo ọjọ́ Lameki si jẹ ẹgbẹrin ọdún o dí mẹtalelogun: o si kú.

32. Noa si jẹ ẹni ẹ̃dẹgbẹta ọdún: Noa si bí Ṣemu, Hamu, ati Jafeti.

Gẹn 5