Gẹn 5:24-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Enoku si ba Ọlọrun rìn: on kò si sí; nitori ti Ọlọrun mu u lọ.

25. Metusela si wà li ọgọsan ọdún o lé meje, o si bí Lameki:

26. Metusela si wà li ẹgbẹrin ọdún o dí mejidilogun lẹhin igbati o bí Lameki, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin:

27. Gbogbo ọjọ́ Metusela si jẹ ẹgbẹrun ọdún o dí mọkanlelọgbọ̀n: o si kú.

28. Lameki si wà li ọgọsan ọdún o lé meji, o si bí ọmọkunrin kan:

29. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Noa, pe, Eleyi ni yio tù wa ni inu ni iṣẹ ati lãla ọwọ́ wa, nitori ilẹ ti OLUWA ti fibú.

Gẹn 5